Revelation of John 19

Haleluya

1Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo gbọ́ ohùn ńlá ní ọ̀run bí ẹni pé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, ń wí pé:

“Haleluya!
Ti Olúwa Ọlọ́run wa ni ìgbàlà, àti ọlá àti agbára,
2 anítorí òtítọ́ àti òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀.
Nítorí o ti ṣe ìdájọ́ àgbèrè ńlá a nì,
tí o fi àgbèrè rẹ̀ ba ilẹ̀ ayé jẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ náà.”
3 bÀti lẹ́ẹ̀kejì wọ́n wí pé:

“Haleluya!
Èéfín rẹ̀ sì gòkè lọ láé àti láéláé.”
4Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún nì, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nì sì wólẹ̀, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wí pé:

“Àmín, Haleluya!”
5 cOhùn kan sì ti ibi ìtẹ́ náà jáde wá, wí pé:

“Ẹ máa yin Ọlọ́run wa,
ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo,
ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
àti èwe àti àgbà!”
6Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńláńlá, ń wí pé:

“Haleluya!
Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jẹ ọba.
7 dẸ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi,
kí a sì fi ògo fún un.
Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé,
aya rẹ̀ sì ti múra tán.
8Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀
wíwẹ́ tí ó funfun gbòò.”
(Nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ nì dúró fún iṣẹ́ òdodo àwọn ènìyàn mímọ́.)

9Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, ‘Ìbùkún ni fún àwọn tí a pè sí àsè alẹ́ ìgbéyàwó ọ̀dọ́-àgùntàn.’ ” Ó sì wí fún mi pé: “Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.”

10Mo sì wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ láti foríbalẹ̀ fún un. Ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n di ẹ̀rí Jesu mú. Foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run: nítorí pé ẹ̀rí Jesu ni ìsọtẹ́lẹ̀.”

Ẹni tó gun ẹṣin funfun

11 eMo sì rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, sì wò ó, ẹṣin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni à ń pè ní Olódodo àti Olóòtítọ́, nínú òdodo ni ó sì ń ṣe ìdájọ́, tí ó ń jagun. 12 fOjú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́-iná, àti ní orí rẹ̀ ni adé púpọ̀ wà; ó sì ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnikẹ́ni kò mọ́, bí kò ṣe òun tìkára rẹ̀. 13A sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí a tẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀: a sì ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 14Àwọn ogun tí ń bẹ ní ọ̀run tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, funfun àti mímọ́, sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lórí ẹṣin funfun. 15 gÀti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi sá àwọn orílẹ̀-èdè: “Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn.” Ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè. 16 hÓ sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ:

ọba àwọn ọba àti olúwa àwọn olúwa.
17 iMo sì rí angẹli kan dúró nínú oòrùn; ó sì fi ohùn rara kígbe, ó ń wí fún gbogbo àwọn ẹyẹ tí ń fò ní agbede-méjì ọ̀run pé: “Ẹ wá ẹ sì kó ara yín jọ pọ̀ sí àsè ńlá Ọlọ́run; 18kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ẹran-ara àwọn ọba, àti ẹran-ara àwọn olórí ogun àti ẹran-ara àwọn ènìyàn alágbára, àti ẹran àwọn ẹṣin, àti ti àwọn tí ó jókòó lórí wọn, àti ẹran-ara ènìyàn gbogbo, àti ti òmìnira, àti ti ẹrú, àti ti èwe àti ti àgbà.”

19Mo sì rí ẹranko náà àti àwọn ọba ayé, àti àwọn ogun wọn tí a gbá jọ láti bá ẹni tí ó jókòó lórí ẹṣin náà àti ogun rẹ̀ jagun. 20A sì mú ẹranko náà, àti wòlíì èké nì pẹ̀lú rẹ̀, tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ ìyanu níwájú rẹ̀, èyí tí ó fi ń tan àwọn tí ó gba ààmì ẹranko náà àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀ jẹ. Àwọn méjèèjì yìí ni a sọ láààyè sínú adágún iná tí ń fi sulfuru jó. 21Àwọn ìyókù ni a sì fi idà ẹni tí ó jókòó lórí ẹṣin náà pa, àní idà tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde: Gbogbo àwọn ẹyẹ sì ti ipa ẹran-ara wọn yó.

Copyright information for YorBMYO